Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 97:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa jọba, jẹ́ kí ayé kí o yọ̀jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn

2. Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yí káòdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ Rẹ̀.

3. Iná ń jó níwájú Rẹ̀. O sì ń jó àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yíká kiri

4. Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn ó sí kárí ayéayé rí i ó sì wárìrì

5. Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6. Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo Rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo Rẹ̀.

7. Gbogbo àwọn tí ń sin òrìṣà ni ojú yóò ti,àwọn ti n fi ère ṣe àfẹ́rí ara wọnẸsìn ín, ẹ̀yin òrìṣà;

8. Síónì gbọ́, inú Rẹ̀ sì dùnìnú àwọn ilé Júdà sì dùnNítorí ìdájọ́ Rẹ, Olúwa

9. Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ní ó ga ju gbogbo ayé lọìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìsà lọ.

10. Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórira ibi, ó pa ọkan àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ mọ́ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11. Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodoàti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn

12. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,kí ẹ sì yin orúkọ Rẹ̀ mímọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 97