10. Sọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, “Olúwa jọbaa fi ìdí ayé mú lẹ̀, tí kò sì lè yí;ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.”
11. Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì dùnjẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú ohungbogbo tí ń bẹ nínú Rẹ̀.
12. Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀àti ohun gbogbo ti ń bẹ nínú Rẹ̀:nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13. Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,nítorí ti ó ń bọ́ wá,òun bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayéyóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayéàti ti àwọn ènìyàn ni yóò fí òtítọ́ Rẹ̀ ṣe.