Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 96:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2. Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ Rẹ̀ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3. Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn.

4. Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ sí;òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìsà lọ

5. Nítorí aṣán ni gbogbo àwọn òrìsà orílẹ̀ èdèṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run

6. Ọlá àti ọlá ńlá wà ni ìwájú Rẹ̀agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

7. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ yin ìbátan ènìyànẸ fi agbára àti ògo fún Olúwa

8. Ẹ fi ògo tí o tọ́ sí Olúwa fún un;ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá Rẹ̀

9. Ẹ máa sin Olúwa ninú ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀;ẹ wárìrì níwájú Rẹ̀ gbogbo ayé.

10. Sọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, “Olúwa jọbaa fi ìdí ayé mú lẹ̀, tí kò sì lè yí;ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.”

11. Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì dùnjẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú ohungbogbo tí ń bẹ nínú Rẹ̀.

12. Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀àti ohun gbogbo ti ń bẹ nínú Rẹ̀:nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 96