Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 95:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlòorin àti ìyìn.

3. Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

4. Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.

5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá aàti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a forí balẹ̀ kí a sìn-ín,Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa;

7. Nítorí òun ni Ọlọ́run waàwa sì ni ènìyàn pápá Rẹ̀,àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ Rẹ̀Lónìí ti ìwọ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀,

8. Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Méríbà,àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ni Másà ni ihà,

9. Nígbà ti àwọn baba yin dán mi wòti wọn wádìí mi,ti wọn sì ri iṣẹ́ mi

10. Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;mo wí pé, “Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn sáko lọwọn kò sì mọ ọ̀nà mi”.

11. Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi“Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.”

Ka pipe ipin Sáàmù 95