8. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, Olúwa,nítòótọ́ àwọn ọ̀ta Rẹ yóò ṣègbé;gbogbo àwọn olùṣe búburúní a ó fọ́nká.
10. Ìwọ tí gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;òróró dídára ni a dà sími ní orí.
11. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀ta mi;ìparun sí àwọn ènìyàn búburútí ó dìde sí mi.
12. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,wọn yóò dàgbà bí i igi kédárì Lẹ́bánónì;
13. Tí a gbìn si ilé Olúwa,Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14. Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbówọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,