Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 92:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Láti kéde ìfẹ́ Rẹ̀ ní òwúrọ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ ní alẹ́

3. Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàáàti lára ohun èlò orin háàpù.

4. Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùnnípa iṣẹ́ Rẹ Olúwa;èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

5. Báwo ni isẹ́ Rẹ tí tóbi tó, Olúwa,èrò inú Rẹ ìjìnlẹ̀ ni!

6. Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,

7. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburúbá rú jáde bí i koríkoàti gbogbo àwọn olùṣebúburú gbèrú,wọn yóò run láéláé.

8. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

9. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, Olúwa,nítòótọ́ àwọn ọ̀ta Rẹ yóò ṣègbé;gbogbo àwọn olùṣe búburúní a ó fọ́nká.

10. Ìwọ tí gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;òróró dídára ni a dà sími ní orí.

11. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀ta mi;ìparun sí àwọn ènìyàn búburútí ó dìde sí mi.

12. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,wọn yóò dàgbà bí i igi kédárì Lẹ́bánónì;

Ka pipe ipin Sáàmù 92