Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 92:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwaàti láti máa kọrin sí orúkọ Rẹ̀, Ọ̀gá ògo,

2. Láti kéde ìfẹ́ Rẹ̀ ní òwúrọ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ ní alẹ́

3. Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàáàti lára ohun èlò orin háàpù.

4. Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùnnípa iṣẹ́ Rẹ Olúwa;èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

5. Báwo ni isẹ́ Rẹ tí tóbi tó, Olúwa,èrò inú Rẹ ìjìnlẹ̀ ni!

6. Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,

7. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburúbá rú jáde bí i koríkoàti gbogbo àwọn olùṣebúburú gbèrú,wọn yóò run láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 92