Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 90:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntunní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù.

7. A pa wá run nípa ìbínú Rẹnípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá.

8. Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ,àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ,

9. Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú Rẹ;àwa n lo ọjọ wá lọ bí àlá ti a ń rọ́.

10. Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún: wá,tí ó sì ṣe pé nipa agbáratí wọn bá tó ọgọrìn ọdúnagbára wọn làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ninítorí pé a kò ni gé e kúrò,àwa a sì fò lọ.

11. Ta ni ó mọ agbára ìbínú Rẹ?Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù Rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Rẹ.

12. Kọ́ wa bí a ti ń kàye ọjọ́ wa dáradára,kí àwa bá a le fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13. Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ to?Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ.

14. Tẹ́wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ,kí àwa kí o le kọrin fún ayọ̀kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.

15. Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,fún ọjọ́ pípọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.

16. Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀,ògo Rẹ̀ sì àwọn ọmọ wọn.

17. Jẹ́ kí ẹwa Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;fí ìdí iṣẹ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wabẹ́ẹ̀ ní kí ó sì ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 90