7. Olúwa jọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9. Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10. Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́,èmi tàbí ìwọ, Olúwa, kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀.
11. Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ti o ń jọba ní Síónì;kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe.
12. Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13. Olúwa, wo bí àwọn ọ̀ta ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu ọ̀nà ikú,
14. Kí èmi kí o lè sọ ti ìyìn Rẹni ẹnu ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Síónìàti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ.
15. Àwọn orílẹ̀ èdè ti jìn sí kòtò ti wọn ti gbẹ́;ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16. A mọ Olúwa nípa òdodo Rẹ̀;àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17. Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18. Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a ò ní gbàgbé láéláé,ìrètí àwọn ti ó talakà lójú kí yóò ṣègbé láéláé.