Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 9:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Olúwa jọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.

8. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.

9. Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.

10. Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́,èmi tàbí ìwọ, Olúwa, kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀.

11. Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ti o ń jọba ní Síónì;kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe.

Ka pipe ipin Sáàmù 9