Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi o yìn ọ, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;Èmi o sọ ti ìyanu Rẹ gbogbo.

2. Inú mi yóò dùn èmi yóò sì yọ̀ nínú Rẹ;Èmi o kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3. Àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà;Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú Rẹ.

4. Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.

5. Ìwọ ti bá orílẹ̀ èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 9