Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 9:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi o yìn ọ, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;Èmi o sọ ti ìyanu Rẹ gbogbo.

2. Inú mi yóò dùn èmi yóò sì yọ̀ nínú Rẹ;Èmi o kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3. Àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà;Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú Rẹ.

4. Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.

5. Ìwọ ti bá orílẹ̀ èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.

6. Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀ta,Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;Àní ìrántí wọn sì ti sègbé.

7. Olúwa jọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.

8. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.

9. Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.

10. Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́,èmi tàbí ìwọ, Olúwa, kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀.

11. Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ti o ń jọba ní Síónì;kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe.

Ka pipe ipin Sáàmù 9