Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìwọ ń darí ríru omi òkun;nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn pa rọ́rọ́.

10. Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹbí ẹni tí a pa;ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹtú àwọn ọ̀tá Rẹ ká.

11. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ:ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀:ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

12. Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn;Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ.

13. Ìwọ ní apá agbára;agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 89