Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ta ní ó wà ni ọ̀run ti a lè fi we Olúwa?Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fi wé Olúwa?

7. Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọn bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;ó sì ní ibùyìn fún jú gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

8. Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí Rẹìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ Rẹ sì yí ọ ká.

9. Ìwọ ń darí ríru omi òkun;nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn pa rọ́rọ́.

10. Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹbí ẹni tí a pa;ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹtú àwọn ọ̀tá Rẹ ká.

11. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ:ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀:ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

12. Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn;Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ.

13. Ìwọ ní apá agbára;agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.

14. Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ:ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ.

15. Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.

16. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,wọn ń yin òdodo Rẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo.

18. Nítorí tí Olúwa ni asà wa,ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Sáàmù 89