Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:42-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá Rẹ̀ sókè;ìwọ mú gbogbo ọ̀tá Rẹ̀ yọ̀.

43. Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà Rẹ̀ padà,ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.

44. Ìwọ ti mú ògo Rẹ̀ kùnà,ìwọ si wó ìtẹ́ Rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

45. Ìwọ ti gé ọjọ́ èwé Rẹ̀ kúrú;ìwọ si fi ìtìjú bò ó

46. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?Tí ìwọ ó ha fi ara Rẹ pamọ́ títí láé?Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú Rẹ yóò máa jó bí iná?

47. Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tónítorí asán ha ní ìwọ fi sẹ̀dá àwọn ènìyàn!

48. Ta ni yóò wà láàyè tí kò ní rí ìkú Rẹ̀?Ta lo lé sa kúrò nínú agbára isà-òkú?

49. Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àtijọ́ wà,tí ìwọ ti fi òtítọ́ Rẹ̀ búra fún Dáfídì?

50. Rántí, Olúwa, bí àti ń gan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ;bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,

51. Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá Rẹ gàn, Olúwa,tí wọn gan ipaṣẹ̀ Ẹni àmì òróró Rẹ.

52. Olùbùkún ní Olúwa títí láé.Àmín àti Àmín.

Ka pipe ipin Sáàmù 89