Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:33-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ Rẹ,tàbí ṣẹ́ tán sí òtítọ́ mi.

34. Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mí,tàbí kí èmi yí ọ̀rọ̀ tí o ti ẹnu mi jáde padà.

35. Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì.

36. Irú ọmọ Rẹ yóò dúró títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ̀ yóò dúró bí òòrùn níwájú mi.

37. A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela

38. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti sá tì, ìwọ sì kórìíra;ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró Rẹ.

39. Ìwọ tì sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ Rẹ di òfo;ìwọ tàbùkù adé Rẹ nínú ilẹ

40. Ìwọ tí wo gbogbo àwọn odi Rẹ̀ìwọ sọ ibi gíga Rẹ̀ di ahoro.

41. Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;o ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé e Rẹ̀

42. Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá Rẹ̀ sókè;ìwọ mú gbogbo ọ̀tá Rẹ̀ yọ̀.

43. Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà Rẹ̀ padà,ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.

44. Ìwọ ti mú ògo Rẹ̀ kùnà,ìwọ si wó ìtẹ́ Rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

45. Ìwọ ti gé ọjọ́ èwé Rẹ̀ kúrú;ìwọ si fi ìtìjú bò ó

Ka pipe ipin Sáàmù 89