Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:23-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Èmi yóò run àwọn ọ̀tá Rẹ níwájú Rẹèmi yóò lu àwọn tí ó kóríra Rẹ bolẹ̀

24. Òtítọ́ mi àti ìdúróṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú Rẹàti ní orúkọ mi ní a ó gbé ìwo Rẹ ga.

25. Èmi o gbé ọwọ́ Rẹ lórí òkunàti ọwọ́ ọ̀tún Rẹ lórí àwọn odo ńlá

26. Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ní bàbá mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’

27. Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mí,Ẹni gíga jù àwọn ọba ayé.

28. Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.

29. Èmi o fi ìdí irú ọmọ Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

30. “Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀tí wọ́n kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.

31. Tí wọn bá kọ ìlànà mití wọ́n kò sì pa àṣẹ mi mọ́,

32. Nígbà náà ni èmi o fì ọ̀gà bẹ irékọjá wọn wòàti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú ìná:

33. Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ Rẹ,tàbí ṣẹ́ tán sí òtítọ́ mi.

34. Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mí,tàbí kí èmi yí ọ̀rọ̀ tí o ti ẹnu mi jáde padà.

35. Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì.

36. Irú ọmọ Rẹ yóò dúró títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ̀ yóò dúró bí òòrùn níwájú mi.

37. A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela

38. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti sá tì, ìwọ sì kórìíra;ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró Rẹ.

39. Ìwọ tì sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ Rẹ di òfo;ìwọ tàbùkù adé Rẹ nínú ilẹ

40. Ìwọ tí wo gbogbo àwọn odi Rẹ̀ìwọ sọ ibi gíga Rẹ̀ di ahoro.

Ka pipe ipin Sáàmù 89