Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹbí ẹni tí a pa;ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹtú àwọn ọ̀tá Rẹ ká.

11. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ:ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀:ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

12. Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn;Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ.

13. Ìwọ ní apá agbára;agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.

14. Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ:ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ.

15. Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.

16. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,wọn ń yin òdodo Rẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo.

Ka pipe ipin Sáàmù 89