Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 89:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ̀ òtítọ́ Rẹ láti ìran dé ìran.

2. Èmi ó wí pé, ìfẹ́ Rẹ dúró títí láé,pe ìwọ gbe òtítọ́ Rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ.

3. Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mu pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mimo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi.

4. Èmi ó fi ìdí irú ọmọ Rẹ múlẹ̀ títí láéèmí ó sì máa gbe ìtẹ́ Rẹ ró láti ìran dé ìran”.

5. Àwọn ọ̀run yóò mú yín ṣiṣẹ́ ìyanu Rẹ, Olúwa,òtítọ́ Rẹ ní ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

6. Ta ní ó wà ni ọ̀run ti a lè fi we Olúwa?Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fi wé Olúwa?

7. Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọn bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;ó sì ní ibùyìn fún jú gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

8. Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí Rẹìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ Rẹ sì yí ọ ká.

9. Ìwọ ń darí ríru omi òkun;nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn pa rọ́rọ́.

10. Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹbí ẹni tí a pa;ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹtú àwọn ọ̀tá Rẹ ká.

11. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ:ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀:ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

12. Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn;Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ.

13. Ìwọ ní apá agbára;agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.

14. Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ:ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ.

15. Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 89