9. Ojú mi káànú nítorí ìpọ́njú.Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;mo na ọwọ́ mí jáde sí ọ.
10. Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ hàn fún òkú?Àwọn òkú yóò ha dìde láti yín ọ́ bí?
11. A ó ha fi iṣeun ifẹ́ Rẹ hàn ni ibojì bí:Tàbí òtítọ́ Rẹ ni ipò iparun?
12. A ha le mọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ ní òkùnkùn bíàti òdodo Rẹ ní ìlà ìgbàgbé?
13. Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;ní òwúrọ̀ ní àdúrà mí wá sọ́dọ̀ Rẹ.
14. Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mítí ìwọ fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi?
15. Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,èmi múra àti kú;nígbà ti ẹ̀ru Rẹ ba ń bà mí,èmi di gbére-gbère
16. Ìbínú Rẹ ti kọjá lára mi;ìbẹ̀rù Rẹ ti ge mi kúrò
17. Ní gbogbo ọjọ́ ní wọn yí mi ká bí ìkún omi;wọ́n mù mí pátápátá.
18. Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.