Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 87:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ohun ológo ni a sọ nípa Rẹ,ilú Ọlọ́run;

4. “Èmi ó dárúkọ Rákábù àti Bábílónìláàrin àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:Fílístínì pẹ̀lú, àti Tirẹ, pẹ̀lú Kúṣìyóò sọ pé, èyí ni a bí ni Síónì.”

5. Nítòótọ́, tí Síónì ni a ó sọ,“Eléyìí àti eléyì í ni a bí nínú Rẹ̀,àti Ọlọ́run Ọ̀gá ògo ni yóò fìdí Rẹ̀ múlẹ̀.”

6. Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀:“Eléyìí ni a bí ní Síónì.”

7. Àti àwọn olorin àti àwọn ti ń luohun èlò orin yóò wí pé,“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú Rẹ.”

Ka pipe ipin Sáàmù 87