Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 86:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dáyóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, Olúwa;wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀.

10. Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ní Ọlọ́run.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ;fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ.

12. Èmi o yìn ọ, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkan mi;èmi o fògo fún orúkọ Rẹ títí láé

13. Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ̀ si mi;ìwọ ti gba mí kúrò nínú ọ̀gbun ìsà okú.

14. Àwọn onígbéraga ń dojú kọ mí, Ọlọ́run;àti ìjọ̀ àwọn alágbára ń wáọkàn mi kiri,wọn kò sì fi ọ pè.

15. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.

16. Yípadà sí mi kí ó sì ṣàánú fún mi;fún àwọn ènìyàn Rẹ ní agbárakí o sì gba ọ̀dọ́mọ̀kunrin ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ là.

17. Fi àmi hàn mí fun rere,kí àwọn tí ó kóriíra mi le rí,ki ojú le tì wọ́n, nítorí iwọni ó ti tù mi nínú.

Ka pipe ipin Sáàmù 86