Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 85:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìwọ dárí àìṣedédé àwọn ènìyàn Rẹ̀ jìnìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela

3. Ìwọ fi àwọn ìbínú Rẹ sápá kanìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná Rẹ.

4. Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,kí o sì yí ìbínú Rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.

5. Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?Ìwọ yóò ha mú ìbínú Rẹ pẹ́ yìí gbogbo ìran ká?

6. Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,pé kí àwọn ènìyàn Rẹ lè yọ nínú Rẹ?

7. Fi ìfẹ́ Rẹ tí kò le e kùnà hàn wá, Olúwa,Kí o sì fún wa ní ìgbàlà Rẹ.

8. Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, àní ẹni mímọ́ Rẹ̀:Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmòye.

9. Nítòótọ́ ìgbàlà Rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,pé kí ògo Rẹ̀ kí ó le gbé ní ilẹ̀ wa.

10. Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.

11. Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wáòdodo sì bojúwolẹ̀ láti ọ̀run.

12. Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè Rẹ̀ jáde.

Ka pipe ipin Sáàmù 85