Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 83:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

6. Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ara Íṣímaélì,tí Móábù àti ti Hágárì

7. Gébálì, Ámónì àti Ámálékì,Fílítísitíà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tirẹ̀.

8. Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọnláti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Sela

9. Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánìbí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì,

10. Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórítí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù,àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà,

12. Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìníẸni pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13. Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà,bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14. Bí ìna ti i jó ìgbẹ́ ìgbóàti bí ọ̀wọ́ iná ti ń mú òkè-ńlá gbiná,

15. Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle Rẹ lépa wọnja wọn lójú pẹ̀lú ìjì Rẹ

16. fi ìtìjú kún ojú wọnkí àwọn ènìyàn báà lè ṣe àfẹ́rí orúkọ Rẹ àti kí o fí ìjì líle Rẹ dẹ́rùbà ìwọ Olúwa.

17. Jẹ́ kí ojú kí ó ti wọn, kí wọ́n sì dáámù láéláékí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn

18. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:pé ìwọ níkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Ka pipe ipin Sáàmù 83