Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 83:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run, Má ṣe dákẹ́;Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ ẹ́.

2. Wo bí àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,bi àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

3. Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ;wọn gbìmọ̀ lòdì sí àwọn tí ó fẹ.

4. Wọn wí pé, “wá,” ẹ jẹ́ kí a pa wọn run bí orílẹ̀ èdè,kí orúkọ Ísírẹ́lì ma bá a sí ní ìrántí mọ́.

5. Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

6. Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ara Íṣímaélì,tí Móábù àti ti Hágárì

7. Gébálì, Ámónì àti Ámálékì,Fílítísitíà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tirẹ̀.

8. Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọnláti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Sela

9. Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánìbí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì,

10. Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórítí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù,àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà,

12. Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìníẸni pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13. Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà,bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 83