Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 81:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Jósẹ́fùnígbà tí ó la ìlẹ̀ Éjíbítì jáníbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

6. Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúro ní èjìká yín,a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.

7. Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,mo dán an yín wò ní odò Méríbà. Sela

8. “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Ísírẹ́lì.

9. Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrin yín;ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.

10. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run Rẹ,ẹni tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì.Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11. “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;Ísírẹ́lì kò ní tẹríba fún mi.

12. Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọnláti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13. “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmibí Ísírẹ́lì yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,

14. Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọnkí ń sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!

Ka pipe ipin Sáàmù 81