Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 81:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára waẸ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jákọ́bù!

2. Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wátẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

3. Ẹ fún ìpè ni oṣù tuntunàní nígbà ti a yàn;ní ọjọ́ àjọ wa ti ó ni ìrònú.

4. Èyí ni àṣẹ fún Ísírẹ́lì,àti òfin Ọlọ́run Jákọ́bù.

5. Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Jósẹ́fùnígbà tí ó la ìlẹ̀ Éjíbítì jáníbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ka pipe ipin Sáàmù 81