Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 80:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

7. Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run;jẹ́ kí ojú Rẹ tàn sí wa,kí a ba à le gbà wá là.

8. Ìwọ mú àjàrà jáde láti Éjíbítì;ìwọ lé àwọn aláìkọlà jáde, o sì gbìn-ín.

9. Ìwọ sí àyè sílẹ̀ fún un,ìwọ sì mu tọ gbòǹgbò jìnlẹ̀ó sì kún ilẹ̀ náà.

10. A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjijì Rẹ̀,ẹ̀ka Rẹ dàbí kédárì Ọlọ́run.

11. O yọ ẹ̀ka Rẹ̀ sínú òkun,ọwọ́ Rẹ̀ sí odò ńlá nì.

12. Èéṣe tí ìwọ fi wó odi Rẹ̀tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń sa èso Rẹ̀?

13. Ìmọ̀do láti inú igbó ń bàá jẹ́àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

14. Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ, Ọlọ́run!Bo jú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

15. Gbòngbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ti gbìn,àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara Rẹ.

16. A gé àjàrà Rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;ní ìfibú, àwọn ènìyàn Rẹ̀ ń ṣègbé.

17. Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ,ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbékalẹ̀ fún ara Rẹ.

18. Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ;mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ Rẹ.

19. Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run;kí ojú Rẹ̀ kí o tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,kí á ba à lè gbà wá là.

Ka pipe ipin Sáàmù 80