Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 80:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ tiwa, ìwọ olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì;ìwọ tí ó darí Jósẹ́fù bí ọwọ́ ẹran;ìwọ tí o jòkòó lórí ìtẹ́ láàrin Kérúbù, tàn jáde

2. Níwájú Éfúremù, Bẹ́ńjámínì àti Mánásè.Rú agbára Rẹ̀ sókè;wa fún ìgbàlà wa.

3. Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,kí a bà lé gbà wá là

4. Olúwa Ọlọ́run,ìbínú Rẹ̀ yóò ti pẹ́ tósí àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ?

5. Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọnìwọ ti mú wọn wa ẹ̀kún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́

Ka pipe ipin Sáàmù 80