Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:65-70 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

65. Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.

66. Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà;ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé.

67. Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Jósẹ́fù,kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù;

68. Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà,òkè Síónì, èyí tí ó fẹ́ràn.

69. Ó kọ́ ibi mímọ́ Rẹ̀, ibí gíga,gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

70. Ó yan Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;

Ka pipe ipin Sáàmù 78