Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:62-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

62. Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.

63. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

64. A fi àlùfáà wọn fún idà,àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.

65. Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.

66. Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà;ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé.

67. Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Jósẹ́fù,kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù;

68. Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà,òkè Síónì, èyí tí ó fẹ́ràn.

69. Ó kọ́ ibi mímọ́ Rẹ̀, ibí gíga,gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

70. Ó yan Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;

71. Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntànláti jẹ́ olùṣọ́ Àgùntàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì ogún un Rẹ̀.

72. Dáfídì sì ṣọ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;pẹ̀lú ọwọ́ òye ní ó fi darí wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 78