Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:53-65 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

53. Ó dáàbòbò wọ́n dáadáa, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́nṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

54. Bákan náà ní ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ Rẹòkè tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ tí gbà

55. Ó lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú wọnó sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;ó mú àwọn ẹ̀yà Íṣírẹ́lì jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56. Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wòwọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo;wọn kò pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.

57. Gẹ́gẹ́ bí baba wọn, wọn jẹ́ aláìsòdodo gẹ́gẹ́ bi ọrun ẹ̀tàn

58. Wọ́n bí nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;wọn rú owú Rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn

59. Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,inú bí i gidigidi;ó kọ Ísírẹ́lì pátapáta.

60. Ó kọ àgọ́ Ṣílò sílẹ̀,àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn.

61. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

62. Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.

63. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

64. A fi àlùfáà wọn fún idà,àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.

65. Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.

Ka pipe ipin Sáàmù 78