Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:49-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Ó mú kíkorò ìbínú Rẹ̀ wá sí wọn lára,ìrunú àti ikáánú, àti ìpọ́njú,nípa rírán ańgẹ́lì apanirun sí wọn.

50. Ó pèṣè ipa fún ìbínú Rẹ̀òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikúṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-àrùn

51. Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin ÉjíbítìOlórí agbára wọn nínú àgọ́ Ámù

52. Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;ó sọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú ihà.

53. Ó dáàbòbò wọ́n dáadáa, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́nṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

54. Bákan náà ní ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ Rẹòkè tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ tí gbà

Ka pipe ipin Sáàmù 78