Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:25-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì;o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó

26. Ó sṣ́ afẹ́fẹ́ ìlà òòrùn láti ọ̀run wáó mú afẹ́fẹ́ gúsù wá nípa agbára Rẹ̀.

27. Ó rọ ọ̀jọ̀ ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyànrìn etí òkun

28. Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,yíká àgọ́ wọn.

29. Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọnítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

30. Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọ́n fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,

31. Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọnó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀.

32. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú;nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́

33. O fi òpin sí ayé wọn nínú asánàti ọdún wọn nínú ìpayà.

34. Nígbà kígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,wọn yóò wá a kirì;wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

35. Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;wí pé Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn

36. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n-ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́nwọ́n fí ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;

37. Ọkàn wọn kò sòtítọ́ si i,wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú Rẹ̀.

38. Ṣíbẹ̀ ó ṣàánú;ó dárí àìṣedédé wọn jìnòun kò sì pa wọn runnígbà kí ì gbà ló ń dá ìbínú Rẹ̀ dúrókò sì rú ìbínú Rẹ̀ sókè

Ka pipe ipin Sáàmù 78