Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù,ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì,

22. Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́wọn kò sí gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà Rẹ̀

23. Ṣíbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀runó sì sí ilẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;

24. Ó rọ mánà fún àwọn ènìyàn láti jẹ,ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run

25. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì;o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó

26. Ó sṣ́ afẹ́fẹ́ ìlà òòrùn láti ọ̀run wáó mú afẹ́fẹ́ gúsù wá nípa agbára Rẹ̀.

27. Ó rọ ọ̀jọ̀ ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyànrìn etí òkun

28. Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,yíká àgọ́ wọn.

29. Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọnítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

Ka pipe ipin Sáàmù 78