Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n sì tún tẹ̀ṣíwájú láti dẹ́sẹ̀ sí iní ìsọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá ògo ní àgìnjú.

18. Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wònípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún

19. Wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wí pé“Ọlọ́run ha lè tẹ tábìlì ní aṣálẹ̀?

20. Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,odò sì ṣàn lọ́pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹó ha le pèṣè ẹran fún àwọn ènìyàn Rẹ̀”

21. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù,ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì,

22. Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́wọn kò sí gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà Rẹ̀

23. Ṣíbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀runó sì sí ilẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;

24. Ó rọ mánà fún àwọn ènìyàn láti jẹ,ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run

25. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì;o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó

Ka pipe ipin Sáàmù 78