Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 78:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;tẹ́tí Rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2. Èmi ó la ẹnu mi ní òweèmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;

3. Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.

4. Àwa kí yóò pa wọ́n mọ́kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,ní fífí ìyìn Olúwa, àti ipa Rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hànfún ìran tí ń bọ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 78