Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 77:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn,mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5. Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6. Mo rántí orin mi ní òru.Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀,ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ.

7. Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?Kí yóò ha ṣe ojú rere Rẹ̀ mọ́

8. Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ àti àánú Rẹ̀ tí kú lọ láéláé?Ìlérí Rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

9. Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?Ní ìbínú Rẹ̀, ó ha sé ojú rere Rẹ̀ mọ́? Sela

10. Èmí wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,pé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.

11. Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.

12. Èmi ṣàṣárò lórí iṣẹ́ Rẹ gbogbopẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára Rẹ.

13. Ọlọ́run, Ọ̀nà Rẹ jẹ́ mímọ́.Ọlọ́run wo ní ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

14. Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;ìwọ fi agbára Rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.

15. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,àwọn ọmọ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù. Sela

Ka pipe ipin Sáàmù 77