Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 77:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,mo wá Olúwa;ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú.

3. Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run,mo sì kẹ́dùn;mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela

4. Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn,mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5. Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6. Mo rántí orin mi ní òru.Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀,ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 77