Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 77:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,àwọ̀sánmọ̀ fí àrá dáhùn;ọfà Rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú

18. Àrá Rẹ̀ ni a gbọ ní ibi ìjì,ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

19. Ìpa Rẹ̀ gba òkun, ọ̀nà Rẹ ń bẹ nínú òkun,Ọ̀nà la omi alágbára kọ́já ipa Rẹ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,nítòótọ́ a kò rí ojú ẹṣẹ̀ Rẹ̀.

20. Ó tọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹrannípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.

Ka pipe ipin Sáàmù 77