Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 76:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní Júdà ni a mọ Ọlọ́run;orúkọ Rẹ̀ sì lágbára ní Ísírẹ́lì

2. Àgọ́ Rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù,ibùgbé Rẹ̀ ní Síónì.

3. Níbẹ̀ ní o ṣẹ́ ọfà,asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela

4. Iwọ ni ògo àti ọláJu òkè-ńlá íkogun wọ̀nyìí lọ.

5. Àwọn akíkanjú ọkùnrin A kó àwọn akíkanjú ogun ní ìkógunwọn sún oorun ìgbẹ̀yìn wọn;kò sí ọ̀kan nínú àwọn ajaguntó lè gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè.

6. Ní ìfìbú Rẹ, Ọlọ́run Jákọ́bù,àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dúbúlẹ̀ ṣíbẹ̀.

7. Ìwọ nìkan ni o yẹ kí a bẹ̀rù.Ta ló lé dúró níwájú Rẹ nígbà tí ìwọ bá ń bínú?

8. Ìwọ ń ṣe ìdàjọ́ láti ọ̀run,ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ ẹ́:

9. Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,bá dìde láti ṣe ìdájọ́,láti gba àwọn ẹni ìnílára ilẹ̀ náà. Sela

10. Lóòtọ́, ìbínú Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,ẹni tí ó yọ nínú ìbínú Rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara Rẹ ni àmùrè.

Ka pipe ipin Sáàmù 76