Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 74:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké Rẹ̀ sókèláti gé igi igbó dídí.

6. Ṣùgbọ́n nìsìnsìn yìí iṣẹ́ ọnà fínfínní wọn fi àáké òòlù wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà

7. Wọ́n sun ibi mímọ́ Rẹ̀ lulẹ̀wọ́n ba ibùgbé orúkọ Rẹ̀ jẹ́

8. Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátapáta!”Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

9. A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;kò sí wòlíì kankanẹnìkan kan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.

10. Àwọn ọ̀ta yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?Àwọn ọ̀ta yóò ha ba orúkọ Rẹ jẹ́ títí láé?

11. Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ Rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ?Mú-un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ Rẹ kí o sì run wọ́n!

12. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13. Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára Rẹ;Ìwọ fọ́ orí àwọn abàmì ẹ̀dá nínú omi

14. Ìwọ fọ́ orí Lefiatani túútúú, o sì fi se oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá ti ń gbé inú ìjùTìrẹ ní ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;ìwọ fi ìdí òòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.

15. Iwọ ya orísun omi àti iṣàn omi;Ìwọ mú kí odò tó ń ṣàn gbẹ

16. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;ìwọ yà oòrùn àti òsùpá.

17. Ìwọ pààlà etí ayé;Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

Ka pipe ipin Sáàmù 74