Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 74:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára Rẹ;Ìwọ fọ́ orí àwọn abàmì ẹ̀dá nínú omi

14. Ìwọ fọ́ orí Lefiatani túútúú, o sì fi se oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá ti ń gbé inú ìjùTìrẹ ní ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;ìwọ fi ìdí òòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.

15. Iwọ ya orísun omi àti iṣàn omi;Ìwọ mú kí odò tó ń ṣàn gbẹ

16. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;ìwọ yà oòrùn àti òsùpá.

17. Ìwọ pààlà etí ayé;Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18. Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn Rẹ, Olúwabí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ Rẹ jẹ́.

19. Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà Rẹ fún ẹranko ìgbẹ́ búburú;Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn Rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.

20. Bojúwo májẹ̀mu Rẹ,nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.

21. Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjújẹ́ kí àwọn aláìní àti talákà yin orúkọ Rẹ.

22. Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara Rẹ̀ rò;rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.

23. Má ṣe gbàgbé ohun àwọn ọ̀tá Rẹ,bíbú àwọn ọ̀tá Rẹ, tí ó ń pọ̀ síi nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Sáàmù 74