Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 74:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?Èéṣe tí ìbínú Rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá Rẹ?

2. Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,ẹ̀yà ilẹ̀ ìní Rẹ, tí ìwọ ti ràpadàÒkè Síónì, níbi tí ìwọ ń gbé.

3. Yí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ padà sí ìparun ayérayé wọn,gbogbo ìparun yìí tí ọ̀ta ti mú wá sí ibi mímọ́.

4. Àwọn ọ̀tá Rẹ ń bú ramú-ramùláàrin ìja ènìyàn Rẹ,wọ́n ń gbé Àṣìá wọn sókè fún àmì;

5. Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké Rẹ̀ sókèláti gé igi igbó dídí.

6. Ṣùgbọ́n nìsìnsìn yìí iṣẹ́ ọnà fínfínní wọn fi àáké òòlù wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà

7. Wọ́n sun ibi mímọ́ Rẹ̀ lulẹ̀wọ́n ba ibùgbé orúkọ Rẹ̀ jẹ́

8. Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátapáta!”Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

9. A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;kò sí wòlíì kankanẹnìkan kan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.

10. Àwọn ọ̀ta yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?Àwọn ọ̀ta yóò ha ba orúkọ Rẹ jẹ́ títí láé?

11. Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ Rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ?Mú-un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ Rẹ kí o sì run wọ́n!

Ka pipe ipin Sáàmù 74