Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 72:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ Rẹ̀ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;títí tí oṣùpá kò fi ní sí mọ́

8. Yóò máa jọba láti òkun dé òkunàti láti odò títí dé òpin ayé.

9. Àwọn tí ó wà ní ihà yóò tẹríba fún unàwọn ọ̀ta Rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.

10. Àwọn ọba Táṣíṣì àti tí erékùṣùwọn yóò mú ọrẹ wá fún un;àwọn ọba Ṣéba àti Síbàwọn o mú ẹ̀bùn wá fún-un.

11. Gbogbo ọba yóò tẹríba fún-unàti gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sìn ín.

Ka pipe ipin Sáàmù 72