Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 72:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí yóò gba àwọn aláìnínígbà tí ó bá ń ké,tálákà àti ẹní tí kò ni olùrànlọ́wọ́.

13. Yóò káànú àwọn aláìlera àti aláìníyóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.

14. Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipánítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú Rẹ.

15. Yóò sì yè pẹ́!A ó sì fún un ní wúrà Ṣébà.Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún-un nígbà gbogbokí a sì bùkún fún-un lójojúmọ́.

16. Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;ní orí òkè ni kí ó máa dàgbàkí èso Rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lébánónìyóò máa gbá yìn-ìn bí koríko ilẹ̀.

17. Kí orúkọ Rẹ̀ kí o wà títí láé;orúkọ Rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọn bí òòrùn yóò ti pẹ́ tó;wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nipaṣẹ̀ Rẹ.Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

18. Olùbùkún ní Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́li,ẹnìkan ṣoṣo tí ó n ṣe ohun ìyanu.

19. Olùbùkun ni orúkọ Rẹ tí ó lógo títí láé;kí gbogbo ayé kún fún ògo Rẹ.Àmín àti Àmín.

20. Èyí ni ìpàrí àdúrà Dáfídì ọmọ Jéṣè.

Ka pipe ipin Sáàmù 72