Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 72:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,ọmọ aládé ni ìwọ fi òdodo Rẹ fún

2. Yóò ṣe ìdàjọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú òdodoyóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn talákà Rẹ

3. Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyànàti òkè kékèké nípa òdodo

4. Yóò dábò bò àwọn tí a pọ́n lójú láàrin àwọn ènìyànyóò gba àwọn ọmọ aláìní;yóò sì fa àwọn aninilára ya.

5. Àwọn òtòsì àti aláìníyóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,yóò ti pẹ́ tó,láti ìran díran.

6. Yóò dàbí òjò tí o ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀

7. Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ Rẹ̀ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;títí tí oṣùpá kò fi ní sí mọ́

8. Yóò máa jọba láti òkun dé òkunàti láti odò títí dé òpin ayé.

9. Àwọn tí ó wà ní ihà yóò tẹríba fún unàwọn ọ̀ta Rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.

10. Àwọn ọba Táṣíṣì àti tí erékùṣùwọn yóò mú ọrẹ wá fún un;àwọn ọba Ṣéba àti Síbàwọn o mú ẹ̀bùn wá fún-un.

11. Gbogbo ọba yóò tẹríba fún-unàti gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sìn ín.

Ka pipe ipin Sáàmù 72