Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 71:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mo di ẹni ìyanu fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8. Ìyìn Rẹ̀ kún ẹnu mi,o ń sọ ti ọlá Rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo.

9. Má ṣe ta mí nù ni ọjọ́ ogbó miMá ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́

10. Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ òdì sí miàwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀

11. Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;lépa Rẹ̀ kí ẹ sì munítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

12. Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti rànmí lọ́wọ́.

13. Jẹ́ kí wọn kí ó dààmúkí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mikí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkùbò àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14. Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i.

15. Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ,ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀.

16. Èmi ó wá láti wá kéde agbára Olúwa Ọlọ́run;èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan.

17. Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mítítí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.

18. Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí ẹnu di arúgbó tán tí mo sì hewú,Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́runtítí tí èmi o fi ipá re han ìran yìíàti agbára Rẹ fún gbogbo àwọn aráẹ̀yìn, sọ ti agbára sí ìran tí ń bọ̀agbára Rẹ̀ fún àwọn tí yóò wá.

19. Ọlọ́run, Òdodo Rẹ̀ dé ọ̀run,ìwọ tí ó ti ṣe ohun ńláTa ni, Ọlọ́run, tí o dà bí i Rẹ?

20. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí o pọ̀ tí ó sì korò,ìwọ yóò tún sọ ayé mi jíìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókèláti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 71