20. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí o pọ̀ tí ó sì korò,ìwọ yóò tún sọ ayé mi jíìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókèláti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21. Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ miìwọ yóò tù mí nínú ní hà gbogbo.
22. Èmi yóò fi dùùrù mi yìnfún òtítọ́ Rẹ, Ọlọ́run mi;èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrùìwọ ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
23. Ètè mi yóò kígbe fún ìyìnnígbà tí mo bá kọrín ìyìn sí ọ:èmi, ẹni tí o ràpadà.
24. Ahọ́n mí yóò sọ ti òdodo Rẹ ní gbogbo ọjọ́,fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí láraa sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.