Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 71:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nínú Rẹ̀, Olúwa, ní mo ní ààbò;Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

2. Gbà mí kí ó sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo Rẹ;kọ etí Rẹ sími kí o sì gbà mí.

3. Jẹ́ àpáta ààbò mi,nibi tí èmi lè máa lọpa àṣẹ láti gbà mí,nítorí ìwọ ni àpáta àti asà mi.

4. Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,ní ọwọ́ aláìsòdodo àti ìkà ọkùnrin.

5. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Ọlọ́run,ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mí láti ìgbà èwe

6. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;Ìwọ mu mi jáde láti inú ìyá mi wáèmi ó máa yìn ọ títí láé

7. Mo di ẹni ìyanu fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8. Ìyìn Rẹ̀ kún ẹnu mi,o ń sọ ti ọlá Rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo.

9. Má ṣe ta mí nù ni ọjọ́ ogbó miMá ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́

10. Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ òdì sí miàwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 71